1 Chronicles 11

Dafidi di ọba lórí Israẹli

1 aGbogbo àwọn Israẹli kó ara wọn jọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa í ṣe. 2Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Saulu jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Israẹli ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùṣọ́ Israẹli ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”

3Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú Olúwa, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa láti ọwọ́ Samuẹli.

Dafidi borí Jerusalẹmu

4 bDafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀. 5Àwọn ará ìlú Jebusi sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wọ ìhín yìí wá.” Ṣùgbọ́n Dafidi kó ìlú odi Sioni—èyí tí í ṣe ìlú Dafidi.

6Dafidi ti wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tètè kọlu àwọn ará Jebusi ni yóò di olórí àti balógun.” Joabu ọmọ Seruiah sì kọ́kọ́ gòkè lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.

7Dafidi sì ń gbé inú ìlú odi, nítorí náà ni wọ́n fi ń pè é ni ìlú Dafidi. 8Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri; láti Millo yíkákiri; Joabu sì tún ìyókù àwọn ìlú náà ṣe. 9Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ga, ó sì pọ̀ sí i, nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú rẹ̀.

Dafidi alágbára ọkùnrin

10 cÀwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dafidi, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fún ìjọba rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí: 11Èyí sì ni iye àwọn akọni ọkùnrin Dafidi:

Jaṣobeamu ọmọ Hakumoni, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.

12Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Eleasari ọmọ Dodo àwọn ará Ahohi, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára. 13Ó sì wà pẹ̀lú Dafidi ní Pasi-Dammimu nígbà tí àwọn ará Filistini kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà barle. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Filistini. 14Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárín pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Filistini mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.

15Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní Àfonífojì ní orí òkè Refaimu. 16Ní àsìkò náà Dafidi sì ń bẹ nínú ìlú odi, ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Filistini sì ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu. 17Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu? 18Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Filistini, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu ó sì gbé padà tọ Dafidi wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa. 19“Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe ṣe èyí!” ó wí pé. “Ṣé kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dafidi kò ní mu ú.

Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.

20Abiṣai arákùnrin Joabu ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta. 21Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.

22Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò sno (yìnyín dídì), ó sì pa kìnnìún kan 23Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀. 24Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta. 25Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò kà á láàrín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Dafidi sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́.

26Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí:

Asaheli arákùnrin Joabu,
Elhanani ọmọ Dodo láti Bẹtilẹhẹmu,
27Ṣamotu ará Harori,
Helesi ará Peloni
28Ira ọmọ Ikẹsi láti Tekoa,
Abieseri láti Anatoti,
29Sibekai ará Huṣati,
láti ará Ahohi
30Maharai ará Netofa,
Heledi ọmọ Baanah ará Netofa,
31Itai ọmọ Ribai láti Gibeah ní Benjamini,
Benaiah ará Piratoni,
32Hurai láti Àfonífojì Gaaṣi,
Abieli ará Arbati,
33Asmafeti ará Bahurimu
Eliaba ará Ṣaalboni
34Àwọn ọmọ Haṣemu ará Gisoni
Jonatani ọmọ Ṣage ará Harari.
35Ahiamu ọmọ Sakari ará Harari,
Elifali ọmọ Uri
36Heferi ará Mekerati,
Ahijah ará Peloni,
37Hesro ará Karmeli
Naarai ọmọ Esbai,
38Joeli arákùnrin Natani
Mibari ọmọ Hagari,
39Seleki ará Ammoni,
Naharai ará Beroti ẹni tí ó jẹ́ ẹni tí n ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah.
40Ira ará Itri,
Garebu ará Itri,
41Uriah ará Hiti
Sabadi ọmọ Ahlai.
42Adina ọmọ Ṣina ará Reubeni, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Reubeni, àti pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀.
43Hanani ọmọ Maaka.
Jehoṣafati ará Mitini.
44Ussia ará Asiterati,
Ṣama àti Jeieli àwọn ọmọ Hotami ará Aroeri,
45Jediaeli ọmọ Ṣimri,
àti arákùnrin Joha ará Tisi
46Elieli ará Mahafi
Jeribai àti Joṣafia àwọn ọmọ Elnaamu,
Itimah ará Moabu,
47Elieli, Obedi àti Jaasieli ará Mesoba.
Copyright information for YorBMYO